Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ dá 'sọbsidi' padà ló ṣe mú ẹ̀dínwó bá owó epo bẹntiróòlù NNPCL fún oṣù kan? Àlàyé rèé

Bola Tinubu wọ agbada olomi buluu pẹlu fila
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ṣé lóòótọ́ ni pé ìjọba àpapọ̀ fẹ́ẹ́ dá 'sọbsidi' padà ló ṣe mú ẹ̀dínwó bá owó epo bẹntiróòlù NNPCL fún ọgbọ̀n ọjọ́? Àlàyé rèé

Lanaa Ọjọbọ, ọjọ kẹjọ oṣu Kẹwaa ọdun 2026 ni ijọba apapọ kede ẹdinwo (Discount) owo iye epo ti ileeṣẹ NNPCL ba n ta fun ọgbọn ọjọ.

Minisita fun eto iṣuna ati abojuto ọrọ aje, Taiwo Oyedele, lo kede ẹdinwo owo epo naa nibi ipade awọn akọroyin kan l'Abuja.

Amọ latigba ti ikede naa ti waye ni ọpọ eeyan ti n beere pe ki ni ẹdinwo naa ba de gan-an?

Araalu n beere iye ẹdinwo naa, ati pe ṣe ijọba Tinubu fẹẹ da owo iranwọ (Fuel subsidy) to yọ kuro ni 2023 pada ni.

Alaye ijọba apapọ

Atẹ epo bẹntiroolu pẹlu awọn ẹrọ POS meji labẹ rẹ. Awọn aṣọ inuju meji wa nibẹ pẹlu, bẹẹ ni awọn ike epo kan wa loke atẹ naa.

Nigba to n yannana ẹdinwo ta a mọ si discount naa, Minisita fun iṣuna sọ pe awọn awakọ ero ni ẹdinwo naa wa fun ju kaakiri Naijiria.

Oyedele ṣalaye pe ẹdinwo yii ko tumọ si pe ijọba apapọ ti pada si aye sọbsidy, bi ko ṣe pe wọn kan fẹẹ ta epo naa niye ti wọn ra a lai jere kankan ni.

Eyi yoo wa bẹẹ laaarin ọgbọn ọjọ gẹgẹ bi Minisita ṣe sọ.

"A n ṣe ẹdinwo lori bẹntiroolu ti NNPCL ba ta ni asiko yii si ọgbọn ọjọ, pẹlu awọn awakọ igboro ti a ni lọkan ju kaakiri Naijiria.

"Fun idi eyi, ki i ṣe sọbsidi, ijọba kan n sọ pe ẹ jẹ ka ta a niye ti a ra a ni."

Idi ti wọn fi gbe igbesẹ yii bi Oyedele ṣe ṣalaye, ni lati mu idẹrun ba araalu lori iye ti wọn n ra epo, paapaa fun awọn awakọ ero, ki ero to n wọkọ lẹ tun ri idẹrun si i.

Ṣe ₦1,350 ni jala epo kan yoo jẹ?

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ni itẹsiwaju alaye naa, Oyedele sọ pe ki i ṣe pe jala epo kan yoo jẹ ₦1,350 kaakiri awọn ile epo, bi ko ṣe pe o jẹ afojusun ijọba apapọ lati ri i pe bi iye owo epo ba yi lọja agbaye, ko ni I maa nipa inira lori iye owo epo nibi.

Wọn fi kun un pe ₦1,350 yii jẹ afojusun iye ti awọn alagbata epo yoo le ta a fawọn ti yoo tun un ta a .

O wa fun lati jẹ ki iye jala duro ni iye kan ná, dipo ti yoo maa foni lọ soke, ja walẹ lọla.

"Ohun to wa nibẹ ree: Bi epo ba jẹ ₦1,400 fun jala kan lonii, to jẹ ₦1,400 lọla, o daa ju ko jẹ ₦1,500 lonii, ₦1,300 lọla lọ."

Oyedele lo ṣalaye bẹẹ.

O ni idi eyi ni pe lilọ bibọ owo epo ki i jẹ ki eeyan mọ bi yoo ṣe pada duro, bi epo ba si gbowo leri kia, ki i ṣe bẹẹ tete pada walẹ.

Ohun miran ni pe wọn yoo maa ṣe agbeyẹwo iye owo yii loṣoosu, ki i ṣe pe yoo taku si ₦1,350 ti ijọba n fojusun yii lai yi rara.

Gẹgẹ bi Oyedele ṣe wi, ijọba yoo maa gbe ohun to ba yẹ lati mọ fun araalu jade nipa rẹ, ko le baa kun fun akoyawọ ati otitọ.

Ki lo de ti ijọba fi n gbe awọn igbesẹ yii?

Idahun Oyedele si eyi ni pe ijọba n gbe afikun igbesẹ ti yoo mu idẹkun ba araalu, nitori awọn eto to wa nilẹ ko ti i fi gbogbo ara yanju iṣoro ti idile kọọkan n koju latigba ti afikun ti ba owo epo ati owo ọkọ wiwọ

Awọn igbesẹ idẹrun mi-in to tun ni yoo wa ni:

Fifi opin si awọn owo ti ko tọ tawọn kan n gba lọwọ awọn awakọ, eyi to n mu owo mọto wiwọ wọn gogo.

O ni ijọba apapọ yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ijọba ipinlẹ kọọkan lati ri si eyi.

Bakan naa ni lo ijọba apapọ yoo fowo ranṣẹ sawọn idile ti ìṣẹ́ n ṣẹ́, bẹẹ ni wọn yoo ran awọn olokowo kereje lọwọ pẹlu.

Wọn yoo pese afẹfẹ gaasi fawọn ọkọ to n lo o (CNG), pẹlu ero pe araalu yoo jẹre ẹdinwo, owo ti wọn fi n wọ ọkọ yoo si dinku.

Awọn olokowo to ba kọ lati jẹ ki araalu jẹ anfaani ẹdinwo yii yoo foju wina ofin bi ijọba ṣe wi.

Owo ti wọn ba ri lati ara awọn to lufin yoo tun maa wa fun iranlọwọ igbokegbodo ọkọ ni alaye ti ijọba Naijiria sẹ.

Amọ ọpọ araalu ni igbesẹ yii n ru loju, ohun ti wọn si n sọ lori ayelujara ni pe ète oṣelu ni ijọba Aarẹ Bola Tinubu n pa.

Ero awọn mi-in lori ayelujara ni pe ọgbọn ati fa oju araalu mọra ṣaaju idibo 2027 ni eto yii jẹ.

Wọn ni ko sẹni ti ki mọ pe oore ti ijọba n ṣe yii ki i ṣe lasan, oore ti a ṣe fun adiẹ ko gbe ni, bo pẹ titi, a ṣe omitoro ata si ni lẹnu.

Amọ ijọba apapọ ti ni ko si kinni kan lẹyin anfaani toun gbe de yii, bi ko ṣe lati mu idẹrun ba awọn ọmọ Naijiria nikan.